Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 6:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wà ní agbègbè Fílístínì fún oṣù méje,

2. àwọn ará Fílístínì pe àwọn àlùfáà, àti àwọn aláṣọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì sọ pé, “Kí ni kí a ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa? Sọ fún wa bí àwa yóò ti dá a padà sí àyè rẹ̀.”

3. Wọ́n dáhùn wí pé, “Tí ẹ bá dá àpótí ẹ̀rí Olúwa ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà, ẹ má ṣe dá a padà ní òfìfo, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fún un ní ẹbọ ẹ̀bi. Nígbà náà ni a ó mú un yín láradá, ẹ̀yin yóò sì mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi tí ì kúrò lára yín.”

4. Àwọn ará Fílístínì béèrè pé, “Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un?”Wọ́n dáhùn, “Góòlù oníkókó márùn ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn ún, gẹ́gẹ́ bí iye awọn aláṣẹ Fílístínì, nítorí àjàkálẹ̀-àrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín.

5. Mọ àwòrán àrùn oníkókó àti ti eku èlírí yin tí ó ń ba orílẹ̀ èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 6