Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 31:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nígbà tí ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ si ríi pé Ṣọ́ọ̀lù kú, òun náà sì fi idà rẹ̀ pá ara rẹ̀, ó sì kú pẹ̀lú rẹ̀.

6. Ṣọ́ọ̀lù sì kú, àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta, àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọkùrin rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.

7. Nígbà ti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó wà lápa kejì àfonífojì náà, àti àwọn ẹni tí ó wà lápá kejì Jódánì, rí pé àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sá, àti pé Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ ti kú, wọ́n sì fí ìlú sílẹ̀, wọ́n sì sá, àwọn Fílístínì sí wá, wọ́n sì jókòó si ìlú wọn.

8. Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn Fílístínì dé láti bọ́ nǹkán tí ń bẹ lára àwọn tí ó kù, wọ́n sì rí pé, Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta ṣubú ni òkè Gílíbóà.

9. Wọ́n sì gé orí rẹ̀, wọ́n sì bọ ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ lọ ilẹ̀ Fílístínì káàkiri, láti máa sọ ọ́ nígbángba ni ilé òrìṣà wọn, àti láàrin àwọn ènìyàn.

10. Wọ́n sì fi ìhámọ́ra rẹ̀ sí ilé Áṣítárótì: wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ odi Bétísánì.

11. Nígbà tí àwọn ará Jabesi-Gílíádì sì gbọ́ èyí tí àwọn Fílístínì ṣe sí Ṣọ́ọ̀lù.

12. Gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára sì dìde, wọ́n sì fi gbogbo òru náà rìn, wọ́n sì gbé òkú Ṣọ́ọ̀lù, àti okú àwọn ọmọ bibi rẹ̀ kúrò lára odi Bétísánì, wọ́n sì wá sí Jábésì, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀.

13. Wọ́n sì kó egungun wọn, wọ́n sì sin wọ́n lábẹ́ igi kan ní Jábésì, wọ́n sì gba ààwẹ̀ ní ijọ́ méje.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 31