Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 31:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn Fílístínì sì bá Ísírẹ́lì jà: àwọn ọkùnrin Ísírẹlì sì sá níwájú àwọn Fílístínì, àwọn tí ó fi ara pa sì ṣubú ní òkè Gílíbóà.

2. Àwọn Fílístínì sì ń lépa Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ kíkan; àwọn Fílístínì sì pa Jónátanì àti Ábínádábù, àti Mélíkísúà, àwọn ọmọ Ṣọ́ọ̀lù.

3. Ìjà náà sì burú fún Ṣọ́ọ̀lù gidigidi, àwọn tafàtafà si ta á ní ọfà, o sì fi ara pa púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn tafàtafà.

4. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún ẹni tí o ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí ìwọ sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má ba à wá gún mi, àti kí wọn kí ó má bá à fi mí ṣe ẹlẹ́yà.”Ṣùgbọ́n ẹni tí ó rú ẹ̀rù ìhámọ́ra rẹ̀ kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹ̀rù bà á gidigidi. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lù ú.

5. Nígbà tí ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ si ríi pé Ṣọ́ọ̀lù kú, òun náà sì fi idà rẹ̀ pá ara rẹ̀, ó sì kú pẹ̀lú rẹ̀.

6. Ṣọ́ọ̀lù sì kú, àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta, àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọkùrin rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 31