Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 30:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì ṣe nigbà ti Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì bọ̀ sí Síkílágì ní ọjọ́ kẹta, àwọn ará Ámálékì sì ti kọlu Néséfà, àti Síkílágì, wọ́n sì ti kùn ún ní iná.

2. Wọ́n sì kó àwọn obìnrin tí ń bẹ nínú rẹ̀ ní ìgbékùn, wọn kò sì pa ẹnìkan, ọmọdé tàbí àgbà, ṣùgbọ́n wọ́n kó wọn lọ, wọ́n sì bá ọ̀nà tiwọn lọ.

3. Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin sì wọ ìlú, sì wò ó, a ti kun ún ni iná; àti obìnrin wọn, àti ọmọkùnrin wọn àti ọmọbinrin wọn ni a kó ni ìgbèkùn lọ.

4. Dáfídì àti àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún títí agbára kò fi sí fún wọn mọ́ láti sunkún.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 30