Olúwa pe Sámúẹ́lì ní ìgbà kẹ́tà, Sámúẹ́lì sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Élì ó sì wí pé, “Èmi nì yí; nítorí tí ìwọ pè mí.”Nígbà náà ni Élì wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà.