Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 26:16-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nǹkan tí ìwọ ṣe yìí kò dára. Bí Olúwa ti ń bẹ, o tọ́ kí ẹ̀yin ó kú, nítorí pé ẹ̀yin kò pa olúwa yín mọ́, ẹni àmì òróró Olúwa. Ǹjẹ́ sì wo ibi tí ọ̀kọ̀ ọba gbé wà, àti ìgò omi tí ó ti wà ní bi tìmùtìmù rẹ̀.”

17. Ṣọ́ọ̀lù sì mọ ohùn Dáfídì, ó sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí Dáfídì ọmọ mi?”Dáfídì sì wí pé, “Ohùn mi ni, Olúwa mi, ọba.”

18. Òun sì wí pé, “Nítorí kín ni Olúwa mi ṣe ń lépa ìránṣẹ́ rẹ̀? Kín ni èmi ṣe? Tàbí ìwà búburú wo ni ó wà lọ́wọ́ mi.

19. Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, ọba, Olúwa mi, gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. Bí ó bá ṣe Olúwa bá ti rú ọ sókè sí mi, jẹ́ kí òun o gba ẹbọ; ṣùgbọ́n bí o bá sì ṣe pé ọmọ ènìyàn ni, ìfibú ni kí wọn ó jásí níwájú Olúwa; nítorí tí wọn lé mi jáde lónìí kí èmi má baà ní ìpín nínú ilẹ̀ ìní Olúwa, wí pé, ‘Lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn.’

20. Ǹjẹ́ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi ó ṣàn sílẹ̀ níwájú Olúwa; nítorí ọba Ísírẹ́lì jáde láti wá ẹ̀mí mi bi ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá.”

21. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Èmi ti dẹ́sẹ̀: yípadà, Dáfídì ọmọ mi: nítorí pé èmi kì yóò wa ibi rẹ mọ́, nítorí tí ẹ̀mí mi sì ti ṣe ìyebíye lójú rẹ lónìí: wò ó, èmi ti ń hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣìnà jọjọ.”

22. Dáfídì sì dáhùn, ó sì wí pé, “Wò ó, ọ̀kọ̀ ọba! Kí ó sì jẹ́ kí ọkan nínú àwọn ọmọkùnrin rékọjá wá gbà á.

23. Kí Olúwa o san án fún olúkúlùkù bí òdodo rẹ̀ àti bí òtítọ́ rẹ̀: nítorí pé Olúwa tí fi ọ lé mi lọ́wọ́ lónìí, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ nawọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa.

24. Sì wò ó, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí rẹ ti tóbi lónìí lójú mi, bẹ́ẹ̀ ni ki ẹ̀mí mi ó tóbi lójú Olúwa, kí ó sì gbà mí lọ́wọ́ ibi gbogbo.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 26