Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 25:9-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì lọ, wọ́n sì sọ fún Nábálì gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní orúkọ Dáfídì, wọ́n sì sinmi.

10. Nábálì sì dá àwọn ìránṣẹ Dáfídì lóhùn pé, “Ta ni ń jẹ́ Dáfídì? Tàbí ta ni sì ń jẹ́ ọmọ Jésè? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iránṣe ni ń bẹ ni isinsinyìí tí wọn sá olúkúlùkù kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀.

11. Ǹjẹ́ ki èmi o mú òunjẹ́ mi, àti omi mi, àti ẹran mi ti mo pá fún àwọn olùrẹ́run mi, ki èmi si fi fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò mọ̀ ibi wọ́n ti wá?”

12. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì pada, wọ́n sì wá, wọn si rò fún un gẹ́gẹ́ bi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.

13. Dáfídì sí wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Kí olúkúlùkù yín ó di idá rẹ́ mọ́ idi,” Olúkúlùkù ọkùnrin sì di idà tirẹ́ rẹ́ mọ̀ ìdí; àti Dáfídì pẹ̀lú sì di idà tirẹ̀; ìwọ̀n irinwó ọmọkùnrin si gòkè tọ Dáfídì lẹ́yin; igba si jókòó nibi ẹrù.

14. Ọkan nínú àwọn ọmọkùnrin Nabali si wí fún Ábígáílì aya rẹ̀ pé, “Wo o, Dáfídì rán oníṣẹ́ láti ihà wá láti ki olúwa wa; ó sì kanra mọ́ wọn.

15. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà ṣe oore fún wa gidigidi, wọn kò ṣe wá ní ibi kan, ohunkóhun kò nù ni ọwọ́ wa ni gbogbo ọjọ́ ti àwa bá wọn rìn nígbà ti àwa ń bẹ lóko.

16. Odi ni wọ́n sáà jásí fún wa lọ́sànán, àti lóru, ni gbogbo ọjọ́ ti a fi bá wọn gbé, tí a n bojútó àwọn àgùntàn.

17. Ǹjẹ́, rò ó wò, kí ìwọ sì mọ èyí ti ìwọ yóò ṣe; nítorí pé a ti gbèrò ibi sí olúwa wa, àti sí gbogbo ilé rẹ̀; òun sì jásí ọmọ Bélíálì tí a kò le sọ̀rọ̀ fún.”

18. Ábígáílì sì yára, ó sì mú igba ìṣù àkàrà àti ìgò-ọtí wáìnì méjì, àti àgùntàn márùn-ún, ti a ti ṣè, àti oṣuwọn àgbàdo yíyan márùn-ún, àti ọgọ́rùn-ún ìdì àjàrà, àti igba àkàrà èso ọ̀pọ̀tọ́, ó sì dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

19. Òun sì wí fún àwọn ọmọkùrin rẹ̀ pé, “Má a lọ níwájú mi; wò ó, èmi ń bọ̀ lẹ́yìn yín,” Ṣùgbọ́n òun kò wí fún Nábálì baálé rẹ̀.

20. Bí o ti gun orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sì ń sọ̀kalẹ̀ sí ibi ìkọ̀kọ̀ òkè náà, wò ó, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ níwájú rẹ̀; òun sì wá pàdé wọn.

21. Dáfídì sì ti wí pé, “Ǹjẹ́ lásán ni èmi ti pa gbogbo èyi tí i ṣe ti eléyìí ní ihà, ti ohunkóhun kò sì nù nínú gbogbo èyí ti í ṣe tirẹ̀: òun ni o sì fi ibi san ire fún mi yìí.

22. Bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni ki Ọlọ́run ó ṣe sí àwọn ọ̀ta Dáfídì, bi èmi bá fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú gbogbo èyí tí i ṣe tirẹ̀ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.”

23. Ábígáílì sì rí Dáfídì, ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú Dáfídì, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.

24. Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa mi, fi ẹ̀ṣẹ̀ yìí yá mi: kí ó sì jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, sọ̀rọ̀ létí rẹ, kí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.

25. Olúwa mi, èmi bẹ̀ ọ́ má ka ọkùnrin Bélíálì yìí sí, àní Nábálì: nítorí pé bí orúkọ rẹ̀ ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òun náà rí: Nábálì ni orúkọ rẹ̀, àìmoye si wà pẹ̀lú rẹ̀; ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́bìnrin rẹ kò ri àwọn ọmọkùnrin olúwa mi, ti ìwọ rán.

26. “Ǹjẹ́ Olúwa mi, bi Olúwa ti wà láàyè, àti bí ẹ̀mí rẹ̀ si ti wà láàyè, bi Olúwa sì ti dá ọ dúró láti wá ta ẹ̀jẹ̀ silẹ̀, àti láti fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san; ǹjẹ́, kí àwọn ọ̀ta rẹ, àti àwọn ẹni tí ń gbérò ibi sí olúwa mi rí bi Nábálì.

27. Ǹjẹ́ èyí ni ẹ̀bùn tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi, jẹ́ kí a sì fi fún àwọn ọmọkùnrin ti ń tọ olúwa mi lẹ́yìn.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 25