Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 25:23-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ábígáílì sì rí Dáfídì, ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú Dáfídì, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.

24. Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa mi, fi ẹ̀ṣẹ̀ yìí yá mi: kí ó sì jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, sọ̀rọ̀ létí rẹ, kí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.

25. Olúwa mi, èmi bẹ̀ ọ́ má ka ọkùnrin Bélíálì yìí sí, àní Nábálì: nítorí pé bí orúkọ rẹ̀ ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òun náà rí: Nábálì ni orúkọ rẹ̀, àìmoye si wà pẹ̀lú rẹ̀; ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́bìnrin rẹ kò ri àwọn ọmọkùnrin olúwa mi, ti ìwọ rán.

26. “Ǹjẹ́ Olúwa mi, bi Olúwa ti wà láàyè, àti bí ẹ̀mí rẹ̀ si ti wà láàyè, bi Olúwa sì ti dá ọ dúró láti wá ta ẹ̀jẹ̀ silẹ̀, àti láti fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san; ǹjẹ́, kí àwọn ọ̀ta rẹ, àti àwọn ẹni tí ń gbérò ibi sí olúwa mi rí bi Nábálì.

27. Ǹjẹ́ èyí ni ẹ̀bùn tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi, jẹ́ kí a sì fi fún àwọn ọmọkùnrin ti ń tọ olúwa mi lẹ́yìn.

28. Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọjá arábìnrin rẹ jìn ní: nítorí Olúwa yóò fi ìdí ìjọba olúwa mi múlẹ̀, nítorí pé ó ja ogun Olúwa. Nítorí náà kí a má ri ibi kan ni ọwọ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí ó wà láàyè.

29. Bí ọkùnrin kan bá sì dìde láti máa lépa rẹ, àti máa wá ẹ̀mí rẹ, a ó sì di ẹ̀mí olúwa mi mú láàyè lọdọ Olúwa Ọlọ́run rẹ; àti ẹ̀mí àwọn ọ̀ta rẹ ni a ó sì gbọ̀n sọnù gẹ́gẹ́ bí kànnàkànnà jáde.

30. Yóò sì ṣe, Olúwa yóò ṣe sí olúwa mi gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìre tí ó ti wí nípa tirẹ̀, yóò sì yàn ọ́ ni aláṣẹ lórí Ísírẹ́lì.

31. Èyí kì yóò sì jásí ìbànújẹ fún ọ, tàbí ìbànújẹ́ ọkàn fún olúwa mi, nítorí pé ìwọ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, tàbí pé olúwa mi gbẹ̀san fún ara rẹ̀: ṣùgbọ́n nígbà tí Olúwa ba ṣe oore fún olúwa mi, ǹjẹ́ rántí ìránṣẹ́bìnrin rẹ!”

32. Dáfídì sì wí fún Ábígáílì pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi.

33. Ìbùkún ni fún ọgbọ́n rẹ, alábùkún sì ni ìwọ, tí ó da mi dúró lónìí yìí láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ mi gbẹ̀san fún ara mi.

34. Nítòòtọ́ ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí ń bẹ, tí ó da mi dúró láti pa ọ́ lára bí kò ṣe pé bí ìwọ ti yára tí ó sì wá pàdé mi, nítòótọ́ kì bá tí kù fún Nábálì di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀.”

35. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì gba nǹkan tí ó mú wá fún un lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Gòkè lọ ni àlàáfíà sí ilé rẹ, wò ó, èmi ti gbọ́ ohùn rẹ, inú mi sì dùn sí ọ.”

36. Ábígáílì sì tọ Nábálì wá, sì wò ó, òun sì ṣe àṣè ni ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àsè ọba: inú Nábálì sì dùn nítorí pé, ó ti mú ọtí ni àmupara; òun kò si sọ nǹkan fún un, díẹ̀ tàbí púpọ̀: títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀

37. Ó sì ṣe; ni òwúrọ̀, nígbà ti ọtí náà si dá tán lójú Nábálì, obìnrin rẹ̀ si ro nǹkan wọ̀nyí fún un, ọkàn rẹ sì kú nínú rẹ̀, òun sì dàbí òkúta.

38. Ó sì ṣe lẹ́yin ìwọ̀n ijọ mẹ́wàá, Olúwa lu Nábálì, ó sì kú.

39. Dáfídì sì gbọ́ pé Nábálì kú, ó sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí o gbéjà gígàn mi láti ọwọ́ Nábálì wá, tí ó sì dá ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró láti ṣe ibi: Olúwa sì yí ikà Nábálì sí orí òun tìkárarẹ̀.”Dáfídì sì ránṣẹ́, ó sì ba Ábígáílì sọ̀rọ̀ láti mú un fi ṣe aya fún ara rẹ̀.

40. Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì lọ sọ́dọ̀ Ábígáílì ni Kamẹ́lì, wọn sì sọ fún un pé, “Dáfídì rán wá si ọ láti mu ọ ṣe aya rẹ̀.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 25