Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 25:21-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Dáfídì sì ti wí pé, “Ǹjẹ́ lásán ni èmi ti pa gbogbo èyi tí i ṣe ti eléyìí ní ihà, ti ohunkóhun kò sì nù nínú gbogbo èyí ti í ṣe tirẹ̀: òun ni o sì fi ibi san ire fún mi yìí.

22. Bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni ki Ọlọ́run ó ṣe sí àwọn ọ̀ta Dáfídì, bi èmi bá fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú gbogbo èyí tí i ṣe tirẹ̀ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.”

23. Ábígáílì sì rí Dáfídì, ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú Dáfídì, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.

24. Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa mi, fi ẹ̀ṣẹ̀ yìí yá mi: kí ó sì jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, sọ̀rọ̀ létí rẹ, kí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.

25. Olúwa mi, èmi bẹ̀ ọ́ má ka ọkùnrin Bélíálì yìí sí, àní Nábálì: nítorí pé bí orúkọ rẹ̀ ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òun náà rí: Nábálì ni orúkọ rẹ̀, àìmoye si wà pẹ̀lú rẹ̀; ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́bìnrin rẹ kò ri àwọn ọmọkùnrin olúwa mi, ti ìwọ rán.

26. “Ǹjẹ́ Olúwa mi, bi Olúwa ti wà láàyè, àti bí ẹ̀mí rẹ̀ si ti wà láàyè, bi Olúwa sì ti dá ọ dúró láti wá ta ẹ̀jẹ̀ silẹ̀, àti láti fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san; ǹjẹ́, kí àwọn ọ̀ta rẹ, àti àwọn ẹni tí ń gbérò ibi sí olúwa mi rí bi Nábálì.

27. Ǹjẹ́ èyí ni ẹ̀bùn tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi, jẹ́ kí a sì fi fún àwọn ọmọkùnrin ti ń tọ olúwa mi lẹ́yìn.

28. Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọjá arábìnrin rẹ jìn ní: nítorí Olúwa yóò fi ìdí ìjọba olúwa mi múlẹ̀, nítorí pé ó ja ogun Olúwa. Nítorí náà kí a má ri ibi kan ni ọwọ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí ó wà láàyè.

29. Bí ọkùnrin kan bá sì dìde láti máa lépa rẹ, àti máa wá ẹ̀mí rẹ, a ó sì di ẹ̀mí olúwa mi mú láàyè lọdọ Olúwa Ọlọ́run rẹ; àti ẹ̀mí àwọn ọ̀ta rẹ ni a ó sì gbọ̀n sọnù gẹ́gẹ́ bí kànnàkànnà jáde.

30. Yóò sì ṣe, Olúwa yóò ṣe sí olúwa mi gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìre tí ó ti wí nípa tirẹ̀, yóò sì yàn ọ́ ni aláṣẹ lórí Ísírẹ́lì.

31. Èyí kì yóò sì jásí ìbànújẹ fún ọ, tàbí ìbànújẹ́ ọkàn fún olúwa mi, nítorí pé ìwọ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, tàbí pé olúwa mi gbẹ̀san fún ara rẹ̀: ṣùgbọ́n nígbà tí Olúwa ba ṣe oore fún olúwa mi, ǹjẹ́ rántí ìránṣẹ́bìnrin rẹ!”

32. Dáfídì sì wí fún Ábígáílì pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi.

33. Ìbùkún ni fún ọgbọ́n rẹ, alábùkún sì ni ìwọ, tí ó da mi dúró lónìí yìí láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ mi gbẹ̀san fún ara mi.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 25