Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 25:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sámúẹ́lì sì kú; gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì sunkún rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ilé rẹ̀ ní Rama.Dáfídì sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Páránì.

2. Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Máónì, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Kámẹ́lì; ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún ewúrẹ́: ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Kámẹ́lì.

3. Orúkọ ọkùnrin náà sì ń jẹ́ Nábálì, orúkọ aya rẹ̀ ń jẹ́ Ábígáílì; òun sì jẹ́ olóye obìnrin, àti arẹwà ènìyàn; ṣùgbọ́n òǹrorò àti oníwà búburú ni ọkùnrin; ẹni ìdílé Kálẹ́bù ni òun jẹ́.

4. Dáfídì sì gbọ́ ní ihà pé Nábálì ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀.

5. Dáfídì sì rán ọmọkùnrin mẹwàá, Dáfídì sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé, “Ẹ gòkè lọ sí Kámẹ́lì, kí ẹ sì tọ Nábálì lọ, kí ẹ sì kí i ni orúkọ mi.

6. Báyìí ni ẹ ó sì wí fún ẹni tí ó wà ni ìrora pé, ‘Àlàáfíà fún ọ! Àlàáfíà fún ohun gbogbo tí ìwọ ní!

7. “ ‘Ǹjẹ́ mo gbọ́ pé, àwọn olùrẹ̀run ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ Wò ó, àwọn olùsọ́ àgùntàn rẹ ti wà lọ́dọ̀ wa àwa kò sì pà wọ́n lára, wọn kò sì sọ ohunkóhun nù ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà ní Kámẹ́lì.

8. Bi àwọn ọmọkùnrin rẹ léèrè, wọn ó sì sọ fún ọ. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí rí ojú rere lọ́dọ̀ rẹ; nítorí pé àwa sá wá ní ọjọ́ àṣè: èmi bẹ̀ ọ́ ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà, fi fún àwọn ìránṣe rẹ, àti fún Dáfídì ọmọ rẹ.’ ”

9. Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì lọ, wọ́n sì sọ fún Nábálì gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní orúkọ Dáfídì, wọ́n sì sinmi.

10. Nábálì sì dá àwọn ìránṣẹ Dáfídì lóhùn pé, “Ta ni ń jẹ́ Dáfídì? Tàbí ta ni sì ń jẹ́ ọmọ Jésè? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iránṣe ni ń bẹ ni isinsinyìí tí wọn sá olúkúlùkù kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 25