Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 24:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ó sì wí fún Dáfídì pé, “Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ; nítorí pé ìwọ ti fi ire san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ.

18. Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí: nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti fi èmi mi lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì pa mí.

19. Nítorí pé bí ènìyàn bá rí ọta rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní àlàáfíà bí? Olúwa yóò sì fi ire san èyí ti ìwọ́ ṣe fún mi lónìí.

20. Wò ó, èmi mọ̀ nísinsin yìí pé, nítòótọ́ ìwọ ó jẹ ọba, àti pé ìjọba Ísírẹ́lì yóò sì fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ.

21. Sì búra fún mi nísinsin yìí ní orúkọ Olúwa, pé, ìwọ kì yóò gé irú ọmọ mi kúrò lẹ́yin mi, àti pé, ìwọ kì yóò pa orukọ mi run kúrò ní ìdílé baba mi.”

22. Dáfídì sì búra fún Ṣọ́ọ̀lù. Ṣọ́ọ̀lù sì lọ sí ilé rẹ̀; ṣùgbọ́n Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ sí ihò náà.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 24