Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 24:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Kí Olúwa ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ìwọ, àti kí Olúwa ó gbẹ̀san mi lára rẹ; ṣùgbọ́n, ọwọ́ mi kì yóò sí lara rẹ.

13. Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwá-búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá; ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ.

14. “Nítorí ta ni ọba Ísírẹ́lì fi jáde? Ta ni ìwọ ń lépa? Òkú ajá, tàbí eṣinṣin?

15. Kí Olúwa ó ṣe onídájọ́, kí ó sì dájọ́ láàrin èmi àti ìwọ, kí ó sì gbéjà mi, kí ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ.”

16. Ó sì ṣe, nígbà tí Dáfídì sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí, Dáfídì ọmọ mi?” Ṣọ́ọ̀lù sì gbé ohùn rẹ̀ sòkè, o sunkún.

17. Ó sì wí fún Dáfídì pé, “Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ; nítorí pé ìwọ ti fi ire san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ.

18. Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí: nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti fi èmi mi lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì pa mí.

19. Nítorí pé bí ènìyàn bá rí ọta rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní àlàáfíà bí? Olúwa yóò sì fi ire san èyí ti ìwọ́ ṣe fún mi lónìí.

20. Wò ó, èmi mọ̀ nísinsin yìí pé, nítòótọ́ ìwọ ó jẹ ọba, àti pé ìjọba Ísírẹ́lì yóò sì fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ.

21. Sì búra fún mi nísinsin yìí ní orúkọ Olúwa, pé, ìwọ kì yóò gé irú ọmọ mi kúrò lẹ́yin mi, àti pé, ìwọ kì yóò pa orukọ mi run kúrò ní ìdílé baba mi.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 24