Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 23:27-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Ṣùgbọ́n oníṣẹ́ kan sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá ó sì wí pé, “Ìwọ yára kí o sì wá, nítorí tí àwọn Fílístínì ti gbé ogun ti ilẹ̀ wa.”

28. Ṣọ́ọ̀lù sì padà kúrò ní lilépa Dáfídì, ó sì lọ pàdé àwọn Fílístínì nítorí náà ni wọ́n sì ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní òkúta ìpínyà.

29. Dáfídì sì gòkè láti ibẹ̀ lọ, ó sì jókòó níbi tí ó sápamọ́ sí ní Éńgédì.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 23