Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 23:21-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nípa Olúwa; nítorí pé ẹ̀yin ti káàánú fún mi.

22. Lọ, èmi bẹ̀ yín, ẹ tún múra, kí ẹ sì mọ̀ ki ẹ si rí ibi tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ gbé wà, àti ẹni tí ó rí níbẹ̀: nítorí tí a ti sọ fún mi pé. Ọgbọ́n ni ó ń lò jọjọ.

23. Ẹ sì wo, kí ẹ sì mọ ibi ìsápamọ́ tí ó máa ń sápamọ́ sí, kí ẹ sì tún padà tọ̀ mí wá, kí èmi lè mọ̀ dájú; èmi ó sì bá yín lọ: yóò sì ṣe bí ó bá wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, èmi ó sì wá a ní àwárí nínú gbogbo ẹgbẹ̀rún Júdà!”

24. Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Ṣọ́ọ̀lù lọ sí Sífì: ṣùgbọ́n Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní ihà Máónì, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúsù ti Jésímónì.

25. Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ ń wá a. Wọ́n sì sọ fún Dáfídì: ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí ibi òkúta kan, ó sì jókòó ní ihà ti Máónì. Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́, ó sì lépa Dáfídì ní ihà Máónì.

26. Ṣọ́ọ̀lù sì ń rin apákan òkè kan, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní apákejì òkè náà. Dáfídì sì yára láti sá kúrò níwájú Ṣọ́ọ̀lù; nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti rọ̀gbà yí Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ká láti mú wọn.

27. Ṣùgbọ́n oníṣẹ́ kan sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá ó sì wí pé, “Ìwọ yára kí o sì wá, nítorí tí àwọn Fílístínì ti gbé ogun ti ilẹ̀ wa.”

28. Ṣọ́ọ̀lù sì padà kúrò ní lilépa Dáfídì, ó sì lọ pàdé àwọn Fílístínì nítorí náà ni wọ́n sì ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní òkúta ìpínyà.

29. Dáfídì sì gòkè láti ibẹ̀ lọ, ó sì jókòó níbi tí ó sápamọ́ sí ní Éńgédì.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 23