Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 22:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Áhímélékì ọmọ Áhítúbì tí a ń pè ní Ábíátarì sì bọ́; ó sì sá àsálà tọ Dáfídì lọ.

21. Ábíátarì sì fi han Dáfídì pé Ṣọ́ọ̀lù pá àwọn àlùfáà Olúwa tán.

22. Dáfídì sì wí fún Ábíátarì pé, “Èmi ti mọ̀ ní ọjọ́ náà, nígbà tí Dóégì ará Édómù ti wà níbẹ̀ pé, nítòótọ́ yóò sọ fún Ṣọ́ọ̀lù: nítorí mi ni a ṣe pá gbogbo ìdílé baba rẹ.

23. Ìwọ jókòó níhin lọ́dọ̀ mi, má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé ẹni ti ń wá ẹ̀mi mi, ó ń wá ẹ̀mí rẹ: Ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ mi ni ìwọ ó wà ní àìléwu.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 22