Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 22:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Dáfídì sì kúrò níbẹ̀, ó sì sá sí ihò Ádúlámù; nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìdílé baba rẹ̀ sì gbọ́, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá níbẹ̀.

2. Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ipọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbésè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn; àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó iwọ̀n irinwó ọmọkùnrin.

3. Dáfídì sì ti ibẹ̀ náà lọ sí Mísípa tí Móábù: ó sì wí fún ọba Móábù pé, “Jẹ́ kí baba àti ìyá mi, èmi bẹ̀ ọ́ wá bá ọ gbé, títí èmi yóò fi mọ ohun ti Ọlọ́run yóò ṣe fún mi.”

4. Ó sì mú wọn wá ṣíwájú ọba Móábù; wọ́n sì bá á gbé ní gbogbo ọjọ́ tí Dáfídì fí wà nínú ihò náà.

5. Gádì wòlíì sí wí fún Dáfídì pé, “Ma ṣe gbé inú ihò náà, yẹra, kí o sí lọ sí ilẹ̀ Júdà.” Nígbà náà ni Dáfídì sì yẹra, ó sì lọ sínú igbó Hárétì.

6. Ṣọ́ọ̀lù si gbọ́ pé a rí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ ní Gíbéà lábẹ́ igi kan ní Rámà; ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 22