Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 21:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Dáfídì sì pa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí í mọ́ ni ọkàn rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Ákíṣì ọba Gátì gidigidi.

13. Òun sì pa ìṣe rẹ̀ dà níwájú wọn, ó sì sọ ara rẹ̀ di aṣiwèrè ní ọwọ́ wọn, ó sì ń fi ọwọ́ rẹ̀ ha ilẹ̀kùn ojú ọ̀nà, ó sì ń wá itọ́ sí irungbọ̀n rẹ̀.

14. Nígbà náà ni Ákíṣì wí fún àwọn ìrańṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wó o, nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe mú un tọ̀ mí wá.

15. Mo há ni un fi aṣiwèrè ṣe? Tí ẹ̀yin fi mú èyí tọ̀ mí wá lati hú ìwà aṣiwèrè níwájú mi? Eléyìí yóò há wọ inú ilé mi?”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 21