Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 21:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Dáfídì sì wá sí Nóbù sọ́dọ̀ Áhímélékì àlùfáà, Áhímélékì sì bẹ̀rù láti pàdé Dáfídì, ó sì wí fún un pé, “Èé ha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ.”

2. Dáfídì sì wí fún Áhímélékì àlùfáà pé, “Ọbá pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí.

3. Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀? Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn ún tabi ohunkohun tí o bá rí.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 21