Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 18:17-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Mérábù. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Ṣọ́ọ̀lù wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè síi. Jẹ́ kí àwọn Fílístínì ṣe èyí.”

18. Ṣùgbọ́n Dáfídì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Ta ni mí, kí sì ni ìdílé mi tàbí ìdílé baba mi ní Ísírẹ́lì, tí èmi yóò di àna ọba?”

19. Nígbà tí àkókò tó fún Mérábù, ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù, láti fi fún Dáfídì, ni a sì fi fún Ádíríélì ara Méhólátì ní aya.

20. Nísinsìn yìí ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù Míkálì sì fẹ́ràn Dáfídì, nígbà tí wọ́n sọ fún Ṣọ́ọ̀lù nípa rẹ̀, ó sì dùn mọ́ ọn.

21. Ó sọ nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò fi fún un kí òun ba à le jẹ́ tàkúté fún un, kí ọwọ́ àwọn ará Fílístínì lè wà lára rẹ̀.” Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Nísinsìn yìí ìwọ ní àǹfààní eléyìí láti jẹ́ àna àn mi.”

22. Ṣọ́ọ̀lù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ fún Dáfídì ní ìkọ̀kọ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Wò ó, inú ọba dùn sí ọ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni ó fẹ́ràn rẹ, nísinsìn yìí jẹ́ àna ọba.’ ”

23. Wọ́n tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún Dáfídì. Ṣùgbọ́n Dáfídì wí pé, “Ṣé ẹ rò pé ohun kékeré ni láti jẹ́ àna ọba? Mo jẹ́ tálákà ènìyàn àti onímọ̀ kékeré.”

24. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sọ fún un ohun tí Dáfídì sọ,

25. Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, “Sọ fún Dáfídì pé, ‘Ọba kò fẹ́ owó orí láti ọ̀dọ̀ àna rẹ̀ ju awọ iwájú orí ọgọ́rùn ún Fílístínì lọ láti fi gba ẹ̀san lórí àwọn ọ̀ta rẹ̀.’ ” Èrò Ṣọ́ọ̀lù ni wí pé kí Dáfídì ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Fílístínì.

26. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún Dáfídì, inú rẹ̀ dùn láti di àna ọba kí àkókò tí ó dá tó kọjá,

27. Dáfídì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ wọ́n sì pa igba lára àwọn Fílístínì. Ó kó awọ iwájú orí wọn wá, ó sì pé iye tí ọba fẹ́ kí ó baà lè jẹ́ àna ọba. Ṣọ́ọ̀lù sì fi ọmọ obìnrin Míkálì fún un ní aya.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 18