Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 18:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò gún Dáfídì pọ̀ mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n, Dáfídì yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì.

12. Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ̀rù Dáfídì nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Dáfídì, ṣùgbọ́n ó ti fi Ṣọ́ọ̀lù sílẹ̀.

13. Ó sì lé Dáfídì jáde ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fi jẹ olórí ogun ẹgbẹ̀rún kan, Dáfídì ń kó wọn lọ, ó ń kó wọn bọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun.

14. Nínú ohun tí ó bá ṣe, ó ń ní àṣeyọrí ńlá, nítorí tí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 18