Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 18:10-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ní ọjọ́ kejì ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pẹ̀lú agbára sórí Ṣọ́ọ̀lù, ó sì sọ àṣọtẹ́lẹ̀ ní ilé rẹ̀ nígbà tí Dáfídì sì ń fọn ohun èlò orin olókùn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe láti ẹ̀yìn wá, Ṣọ́ọ̀lù sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀.

11. Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò gún Dáfídì pọ̀ mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n, Dáfídì yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì.

12. Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ̀rù Dáfídì nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Dáfídì, ṣùgbọ́n ó ti fi Ṣọ́ọ̀lù sílẹ̀.

13. Ó sì lé Dáfídì jáde ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fi jẹ olórí ogun ẹgbẹ̀rún kan, Dáfídì ń kó wọn lọ, ó ń kó wọn bọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun.

14. Nínú ohun tí ó bá ṣe, ó ń ní àṣeyọrí ńlá, nítorí tí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.

15. Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀.

16. Ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà ni wọ́n fẹ́ràn Dáfídì, nítorí ó darí wọn ní ìgbòkègbodò ogun wọn.

17. Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Mérábù. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Ṣọ́ọ̀lù wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè síi. Jẹ́ kí àwọn Fílístínì ṣe èyí.”

18. Ṣùgbọ́n Dáfídì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Ta ni mí, kí sì ni ìdílé mi tàbí ìdílé baba mi ní Ísírẹ́lì, tí èmi yóò di àna ọba?”

19. Nígbà tí àkókò tó fún Mérábù, ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù, láti fi fún Dáfídì, ni a sì fi fún Ádíríélì ara Méhólátì ní aya.

20. Nísinsìn yìí ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù Míkálì sì fẹ́ràn Dáfídì, nígbà tí wọ́n sọ fún Ṣọ́ọ̀lù nípa rẹ̀, ó sì dùn mọ́ ọn.

21. Ó sọ nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò fi fún un kí òun ba à le jẹ́ tàkúté fún un, kí ọwọ́ àwọn ará Fílístínì lè wà lára rẹ̀.” Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Nísinsìn yìí ìwọ ní àǹfààní eléyìí láti jẹ́ àna àn mi.”

22. Ṣọ́ọ̀lù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ fún Dáfídì ní ìkọ̀kọ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Wò ó, inú ọba dùn sí ọ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni ó fẹ́ràn rẹ, nísinsìn yìí jẹ́ àna ọba.’ ”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 18