Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 18:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá Ṣọ́ọ̀lù sọ, ọkàn Jónátanì di ọ̀kan pẹ̀lú ti Dáfídì, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.

2. Láti ọjọ́ náà Ṣọ́ọ̀lù pa Dáfídì mọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì jẹ́ kí ó padà sí ilé baba rẹ̀ mọ́.

3. Jónátanì bá Dáfídì dá májẹ̀mú nítorí tí ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.

4. Jónátanì sì bọ́ aṣọ ìgúnwà, ó sì fi fun Dáfídì pẹ̀lú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti pẹ̀lú idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 18