Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 17:26-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Dáfídì béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Kí ni a ó ò ṣe fún ọkùnrin náà tí ó bá pa Fílístínì yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Ísírẹ́lì? Ta ni aláìkọlà Fílístínì tí ó jẹ́ wí pé yóò máa gan ogun Ọlọ́run alààyè?”

27. Wọ́n tún sọ fún un ohun tí wọ́n ti ń sọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí wọn yóò ṣe fún ọkùnrin tí ó bá pa á.”

28. Nígbà tí Élíábù ẹ̀gbọ́n Dáfídì gbọ́ nígbà tí ó ń bá ọkùnrin yìí sọ̀rọ̀, ó bínú sí i, ó sì wí pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ fi sọ̀kalẹ̀ wá síbí? Àti pé ta ni ìwọ fi àwọn àgùntàn kékeré tó kù ṣọ́ ní ihà? Èmi mọ ìgbéraga rẹ, àti búburú ọkàn rẹ: ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá nìkan láti wòran ogun.”

29. Dáfídì wí pé, “Kí ni mo ṣe nísinsìn yìí? Ǹjẹ́ mo lè sọ̀rọ̀ bí?”

30. Ó sì yípadà sí ẹlòmíràn, ó sì ń sọ̀rọ̀ kán náà, ọkùnrin náà sì dáhùn bí ti ẹni ìṣáájú.

31. Àwọn ènìyàn gbọ́ ohun tí Dáfídì sọ wọ́n sọ fún Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì ránṣẹ́ sí i.

32. Dáfídì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí Fílístínì yìí, ìránṣẹ́ rẹ yóò lọ láti bá a jà.”

33. Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, “Ìwọ kò tó láti jáde lọ pàdé ogun Fílístínì yìí àti láti bá a jà; ọmọdé ni iwọ́, òun sì ti ń jagun láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.”

34. Ṣùgbọ́n Dáfídì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ti ń tọ́jú agbo àgùntàn baba rẹ̀. Nígbà tí kìnìún tàbí àmọ̀tẹ́kùn bá wá láti wá gbé àgùntàn láti inú igbó.

35. Mo sá tẹ̀lé e, mo lù ú, mo sì gba àgùntàn náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tí ó kọjú sí mi, mo fi irun rẹ̀ gbá a mú, mo sì lù ú mo sì pa á.

36. Ìránṣẹ́ rẹ ti pa kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn, aláìkọlà Fílístínì yìí yóò jẹ́ ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pe ogun Ọlọ́run alààyè ní ìjà.

37. Olúwa tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìhàlẹ̀ kìnnìún àti ti ìhàlẹ̀ àmọ̀tẹ́kùn yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ Fílístínì yìí.”Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Lọ kí Olúwa wà pẹ̀lú ù rẹ.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 17