Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 15:4-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù kó àwọn ènìyàn jọ, ó sì ka iye wọn ní Táláémù, wọ́n sì jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (200,000) àwọn ológun ẹlẹ́ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹgbàárún àwọn ọkùnrin Júdà (10,000).

5. Ṣọ́ọ̀lù sì lọ sí ìlú Ámálékì ó sì gọ dè wọ́n ní àfonífojì kan.

6. Nígbà náà ni ó wí fún àwọn Kénáítì pé, “Ẹ lọ, kúrò ní Ámálékì kí èmi má ba à run yín pẹ̀lú wọn; nítorí ẹ̀yin fi àánú hàn fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n gòkè ti Éjíbítì wá.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Kénáítì lọ kúrò láàrin àwọn Ámálékì.

7. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù kọlu àwọn Ámálékì láti Háfílà dé Súrì, tí ó fi dé ìlà oòrùn Éjíbítì.

8. Ó sì mú Ágágì ọba Ámálékì láàyè, ó sì fi idà rẹ̀ kọlu gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.

9. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dá Ágágì sí àti èyí tí ó dára jùlọ nínú àgùntàn àti màlúù àti ọ̀dọ́ àgùntàn àbọ́pa àti gbogbo nǹkan tó dára. Wọ́n kò sì fẹ́ pa àwọn wọ̀nyí run pátapáta ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí kò dára tí kò sì ní láárí ni wọ́n parun pátapáta.

10. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Sámúẹ́lì wá pé:

11. “Èmi káànú gidigidi pé mo fi Ṣọ́ọ̀lù jọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Sámúẹ́lì sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì képe Olúwa ní gbogbo òru náà.

12. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Sámúẹ́lì sì dìde láti lọ pàdé Ṣọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un pé, “Ṣọ́ọ̀lù ti wá sí Kámẹ́lì. Ó ti kọ́ ibìkan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, ó sì ti yípadà, ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Gílígálì.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 15