Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 14:43-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

43. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Jónátanì pé, “Sọ nǹkan tí ìwọ ṣe fún mi.”Jónátanì sì sọ fún un pé, “Mo kàn fi orí ọ̀pá mi tọ́ oyin díẹ̀ wò. Nísinsìn yìí ṣé mo ní láti kú?”

44. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sí mi, bí ìwọ kò bá kú.”

45. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí Jónátanì kú, ẹni tí ó ti mú ìgbàlà ńlá yìí wá fún Ísírẹ́lì? Kí a má rí í! Bí Olúwa ti wà, ọ̀kan nínú irun orí rẹ̀ kì yóò bọ́ sílẹ̀, nítorí tí ó ṣe èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́.” Báyìí ni àwọn ènìyàn gba Jónátanì sílẹ̀, kò sì kú.

46. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù sì dẹ́kun lílépa àwọn Fílístínì, àwọn Fílístínì sì padà sí ìlú wọn.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 14