Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 14:35-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Nígbà náà Ṣọ́ọ̀lù kọ́ pẹpẹ kan fún Olúwa; èyí sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe èyí.

36. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ tọ Fílístínì lọ ní òru, kí a bá wọn jà títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, kí a má sìṣe dá ẹnìkankan sí nínú wọn.”Wọ́n sì wí pé, “Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ̀.”Ṣùgbọ́n àlùfáà wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọ́run níhìn ín.”

37. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé, “Ṣé kí n sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn Fílístínì lọ bí? Ǹjẹ́ ìwọ yóò fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ bí?” Ṣùgbọ́n Olúwa kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.

38. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ wá síhìn ín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olórí ogun, kí a ṣe ìwádìí irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti ṣẹ̀ lónìí.

39. Bí Olúwa tí ó gba Ísírẹ́lì là ti wà, bí ó bá ṣe pé a rí í lára Jónátanì ọmọ mi, ó ní láti kú.” Ṣùgbọ́n ẹnìkankan nínú wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan.

40. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ẹ lọ sí apá kan; èmi àti Jónátanì ọmọ mi yóò lọ sí apá kan.”Gbogbo àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú rẹ.”

41. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì pé, “Fún mi ní ìdáhùn tí ó tọ́.” A sì mú Jónátanì àti Ṣọ́ọ̀lù nípa ìbò dídì, àwọn ènìyàn náà sì yege.

42. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ dìbò láàárin èmi àti Jónátanì ọmọ mi.” Ìbò náà sì mú Jónátanì.

43. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Jónátanì pé, “Sọ nǹkan tí ìwọ ṣe fún mi.”Jónátanì sì sọ fún un pé, “Mo kàn fi orí ọ̀pá mi tọ́ oyin díẹ̀ wò. Nísinsìn yìí ṣé mo ní láti kú?”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 14