Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 14:10-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá wí pé, ‘Ẹ gòkè tọ̀ wá wá,’ àwa yóò gòkè lọ, nítorí èyí ni yóò jẹ́ àmì fún wa pé Olúwa ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́.”

11. Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Fílístínì. Àwọn Fílístínì sì wí pé, “Wò ó! Àwọn Hébérù ń fà jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí.”

12. Àwọn ọkùnrin ìlú olódi náà sì kígbe sí Jónátánì àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Ẹ gòkè tọ̀ wá wá àwa yóò sì kọ́ ọ yín ní ẹ̀kọ́.”Jónátánì sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Gòkè tọ̀ mí lẹ́yìn; Olúwa ti fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́.”

13. Jónátánì lo ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ láti fà gòkè pẹ̀lú ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àwọn Fílístínì sì ṣubú níwájú Jónátánì ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì tẹ̀lé e, ó sì ń pa lẹ́gbẹ̀ ẹ́ rẹ̀.

14. Ní ìkọlù èkíní yìí, Jónátanì àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì pa ogún ọkùnrin ní agbégbé tó tó ìwọ̀n ààbọ̀ sarè ilẹ̀.

15. Nígbà náà ni ìbẹ̀rù bojo bá àwọn ọmọ ogun; àwọn tí ó wà ní ibùdó àti ní pápá, àti àwọn tí ó wà ní ilé ìlú olódi àti àwọn tí ń kó ìkógun, ilẹ̀ sì mì. Ó jẹ́ ìbẹ̀rù tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

16. Àwọn tí ó ń ṣọ́nà fún Sàúlù ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì sì rí àwọn ọmọ ogun ń túká ní gbogbo ọ̀nà.

17. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ ka àwọn ènìyàn kí ẹ sì mọ ẹni tí ó jáde kúrò nínú wa.” Nígbà tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, sì wòó, Jónátanì àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ni kò sì sí níbẹ̀.

18. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Áhíjà pé, “Gbé àpótí Ọlọ́run wá.” Àpótí Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbà náà.

19. Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì ń bá àlùfáà sọ̀rọ̀, ariwo ní ibùdó àwọn Fílístínì sì ń pọ̀ ṣíwájú sí. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún àlùfáà pé, “Dá ọwọ́ rẹ dúró.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 14