Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 11:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ní ọjọ́ kejì Ṣọ́ọ̀lù pín àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí ipa mẹ́ta, wọ́n sì ya wọ àgọ́ àwọn ará Ámónì ní ìṣọ́ òwúrọ̀, wọ́n sì pa wọ́n títí di ìmóju ọjọ́. Àwọn tó kù wọ́n sì fọ́nká, tó bẹ́ẹ̀ tí méjì wọn kò kù sí ibìkan.

12. Àwọn ènìyàn sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Ta ni ó béèrè wí pé, Ṣọ́ọ̀lù yóò ha jọba lórí wa? Mú àwọn ọkùnrin náà wá, a ó sì pa wọ́n.”

13. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù wí pé, “A kì yóò pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí lónìí yìí ni Olúwa gba Ísírẹ́lì là.”

14. Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Gílígálì, kí a lè fi ẹṣẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù múlẹ̀ bí ọba.”

15. Nítorí náà gbogbo ènìyàn lọ sí Gílígálì, wọn sí fí Ṣọ́ọ̀lù jọba ní ìwájú Olúwa. Níbẹ̀, ni wọn ti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ní ìwájú Olúwa, Ṣọ́ọ̀lù àti gbogbo Ísírẹ́lì ṣe àjọyọ̀ ńlà.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 11