Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 11:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Náhásì ará Ámónì gòkè lọ, ó sì dó ti Jabesi-Gílíádì, gbogbo ọkùnrin Jábésì sì wí fún Néhásì pé, “Bá wa ṣe ìpinnú, àwa yóò sì máa sìn ọ́.”

2. Ṣùgbọ́n Náhásì ará Ámónì sì wí fún un pé, “Nípa èyí ni èmi ó ò fi bá a yín ṣe ìpinnu, nípa yíyọ gbogbo ojú ọtún yín kúró, èmi o si fi yín se ẹlẹ́yà lójú gbogbo Ísírẹ́lì.”

3. Àwọn àgbà Jábésì sì wí fún un pé, “Fún wa ní ọjọ́ méje kí àwa lè rán oníṣẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì; àti agbègbè bí ẹni kankan kò bá sì jáde láti gbà wá, àwa yóò fi ara wa fún ọ.”

4. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà sì wá sí Gíbíà tí ó jẹ́ ìlú Ṣọ́ọ̀lù, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, gbogbo wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún.

5. Nígbà náà gan an ni Ṣọ́ọ̀lù padà wá láti pápá, pẹ̀lú màlúù rẹ̀, ó sì béèrè pé, “kín ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn? Èéṣe tí wọ́n fi ń sunkún?” Nígbà náà ni wọ́n tún sọ fún wọn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jábésì.

6. Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e pẹ̀lú agbára, inú rẹ̀ sì ru sókè.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 11