Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 10:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Sámúẹ́lì ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba. Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀.

26. Ṣọ́ọ̀lù náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gíbíà. Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín.

27. Ṣùgbọ́n àwọn oníjàgbọ̀n kan wí pé, “Báwo ni ẹni yìí yóò ṣe gbà wá?” Wọ́n kẹ́gan rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù fọwọ́ lẹ́rán.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 10