Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 10:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: ‘Èmi mú Ísírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Éjíbítì àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’

19. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.”

20. Nígbà Sámúẹ́lì mú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 10