Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 5:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Sólómónì jẹ́ ẹgbẹ̀rindínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún (3,300) ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà.

17. Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀.

18. Àwọn oníṣọ̀nà Sólómónì àti Hírámù àti àwọn ènìyàn Gébálì sì gbẹ́ wọn, wọ́n sì pèsè igi àti òkúta láti fi kọ́ ilé náà.

Ka pipe ipin 1 Ọba 5