Ó sì rán wọn lọ sí Lébánónì, ẹgbàárún (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lébánónì, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Ádónírámù ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà.