Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 4:19-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Gébérì ọmọ Úrì ní Gílíádì; orílẹ̀ èdè Ṣíhónì ọba àwọn ará Ámórì àti orílẹ̀ èdè Ógù ọba Básánì. Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà.

20. Àwọn ènìyàn Júdà àti ti Ísírẹ́lì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí òkun; wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń yọ ayọ̀.

21. Sólómónì sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ijọba láti odò Éjíbítì títí dé ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì, àti títí dé etí ilẹ̀ Éjíbítì. Àwọn orílẹ̀ èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Sólómónì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

22. Oúnjẹ Sólómónì fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n (30) ìyẹ̀fun kíkúná àti ọgọ́ta (60) òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun,

23. Màlúù mẹ́wàá (10) tí ó sanra, àti ogún (20) màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti egbin, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra.

24. Nítorí òun ni ó ṣakóso lórí gbogbo agbègbè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Éfúrátì, láti Tífísà títí dé Gásà, ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo ìlú tí ó káàkiri.

25. Nígbà ayé Sólómónì, Júdà àti Ísírẹ́lì, láti Dánì títí dé Béríṣébà, wọ́n ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.

26. Sólómónì sì ní ẹgbàajì (40,000) ilé ẹsin fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ẹgbàafà (12,000) ẹlẹ́sin.

Ka pipe ipin 1 Ọba 4