1. Sólómónì ọba sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.
2. Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè rẹ̀:Ásáríyà ọmọ Ṣádókù àlùfáà:
3. Élíhóréfù àti Áhíjà àwọn ọmọ Ṣísánì akọ̀wé;Jèhósáfátì ọmọ Áhílúdì ni akọ̀wé ìlú;
4. Bénáyà ọmọ Jéhóíádà ni olórí ogun;Sádókù àti Ábíátarì ni àwọn àlùfáà;
5. Ásáríyà ọmọ Nátanì ni olórí àwọn agbègbè;Sóbúdù ọmọ Nátanì, àlùfáà àti olùgba ọba ní ìmọ̀ràn;
6. Áhísárì ni olùtọ́jú ààfin;Ádónírámù ọmọ Ábídà ni ó ń ṣe olórí iṣẹ́-ìlú
7. Sólómónì sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún.
8. Orúkọ wọn ni wọ̀nyí:Bénhúrì ní ìlú olókè Éfúráímù.
9. Beni-Dékérì ní Mákásì, Ṣáíbímù, Bẹti-Sémésì, àti Eloni-Bétíhánánì;
10. Beni-Hésédì, ní Árúbótì; tirẹ̀ ni Sókò àti gbogbo ilẹ̀ Héférì ń ṣe;
11. Beni-Ábínádábù, ní Napoti Dórì; òun ni ó fẹ́ Táfátì ọmọbìnrin Sólómónì ní aya.