Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 20:36-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí tí ìwọ kò gba ohùn Olúwa gbọ́, kíyèsí i, bí ìwọ bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ́.” Bí ó ti jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan rí i, ó sì pa á.

37. Wòlíì náà sì rí ọkùnrin mìíràn, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí.” Bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin náà sì lù ú, ó sì pa á lára.

38. Wòlíì náà sì lọ, ó sì dúró de ọba ní ojú ọ̀nà. Ó pa ara rẹ̀ dà ní fífi eérú bo ojú.

39. Bí ọba sì ti ń ré kọjá, wòlíì náà ké sí i, ó sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ jáde wọ àárin ogun lọ, ẹnìkan sì wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbékùn kan, ó sì wí pé, ‘Pa ọkùnrin yìí mọ́. Bí a bá fẹ́ ẹ kù, ẹ̀mi rẹ yóò lọ dípò ẹ̀mí rẹ̀, tàbí kí ìwọ san talẹ́ǹtì fàdákà kan.’

40. Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ìṣe níhìn ín àti lọ́hùn ún, a fẹ́ ẹ kù.”Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ìdájọ́ rẹ yóò rí, ìwọ fúnra rẹ ti dá a.”

41. Nígbà náà ni wòlíì náà yára, ó sì mú eérú kúrò ní ojú rẹ̀, ọba Ísírẹ́lì sì mọ̀ ọ́ pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì ni ó ń ṣe.

42. Ó sì wí fún ọba pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ ti jọ̀wọ́ ọkùnrin tí èmi ti yàn sí ìparun pátapáta lọ́wọ́ lọ. Nítorí náà, ẹ̀mí rẹ yóò lọ fún ẹ̀mí rẹ, ènìyàn rẹ fún ènìyàn rẹ̀.’ ”

43. Ọba Ísírẹ́lì sì lọ sí ilé rẹ̀ ní wíwú gbọ, inú rẹ sì bàjẹ́, ó sì wá sí Samáríà.

Ka pipe ipin 1 Ọba 20