Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 20:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bẹni-Hádádì ọba Árámù sì gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ. Ọba méjìlélọ́gbọ̀n sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ àti ẹsin àti kẹ̀kẹ́, ó sì gòkè lọ, ó sì dóti Samáríà, ó sì kọlù ú.

2. Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Áhábù ọba Ísírẹ́lì wí pé, “Báyìí ni Bẹni-Hádádì wí:

3. Sílífà àti wúrà rẹ tèmi ni, àti àwọn tí ó dára jùlọ nínú àwọn aya re àti àwọn ọmọ rẹ tèmi ni wọ́n.”

4. Ọba Ísírẹ́lì sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ṣe wí Olúwa mi ọba, èmi àti ohun gbogbo tí mo ní tìrẹ̀ ni.”

5. Àwọn ońṣẹ́ náà sì tún padà wá, wọ́n sì wí pé, “Báyìí ni Bẹni-Hádádì sọ wí pé: ‘Mo ránṣẹ́ láti béèrè fún fàdákà rẹ àti wúrà rẹ, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ.

6. Ṣùgbọ́n ní ìwòyí ọ̀la Èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ láti wá ilé rẹ wò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Wọn yóò gba gbogbo ohun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò sì kó o lọ.’ ”

Ka pipe ipin 1 Ọba 20