Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 18:28-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kígbe lóhùn rara, wọ́n sì fi ọ̀bẹ àti ọ̀kọ̀ ya ara wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi tú jáde ní ara wọn.

29. Nígbà tí ọjọ́ yẹ àtàrí, wọ́n sì ń fi òmùgọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohùn, kò sì sí ìdáhùn, kò sì sí ẹni tí ó kà á sí.

30. Nígbà náà ni Èlíjà wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi.” Wọ́n sì sún mọ́ ọn, ó sì tún pẹpẹ Olúwa tí ó ti wó lulẹ̀ ṣe.

31. Èlíjà sì mú òkúta méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà ọmọ Jákọ́bù kan, ẹni tí ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ wá wí pé, “Ísírẹ́lì ni orúkọ rẹ̀ yóò máa jẹ́.”

32. Ó sì tẹ́ pẹpẹ pẹ̀lú àwọn òkúta wọ̀nyí ní orúkọ Olúwa, ó sì wa yàrá yí pẹpẹ náà ká, tí ó lè gba ìwọ̀n òṣùwọ̀n irúgbìn méjì.

33. Ó sì to igi náà dáradára, ó sì ké ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù náà wẹ́wẹ́, ó sì tò ó sórí igi. Nígbà náà ni ó sì wí fún wọn wí pé, “Ẹ fi omi kún ìkòkò mẹ́rin, kí ẹ sì tun sórí ẹbọ sísun àti sórí igi náà.”

34. Ó sì wí pe, “Ẹ ṣe é ní ìgbà kejì” Wọ́n sì ṣe é ní ìgbà kejì.Ó sì tún wí pé, “Ṣe é ní ìgbà kẹta.”

35. Omi náà sì ṣàn yí pẹpẹ náà ká, ó sì fi omi kún yàrà náà pẹ̀lú.

36. Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣáálẹ́, wòlíì Èlíjà sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ó di mímọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ.

37. Gbọ́ ti èmi, Olúwa, gbọ́ ti èmi, kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lè mọ̀ pé ìwọ Olúwa ni Ọlọ́run àti pé ìwọ tún yí ọkàn wọn padà.”

38. Nígbà náà ni iná Olúwa bọ́ sílẹ̀, ó sì sun ẹbọ síṣun náà àti igi, àti àwọn Òkúta, àti erùpẹ̀, ó sì tún lá omi tí ń bẹ nínú yàrà náà.

39. Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn sì rí èyí, wọ́n da ojú wọn bolẹ̀, wọ́n sì kígbe pé, “Olúwa, òun ni Ọlọ́run! Olúwa, òun ni Ọlọ́run!”

Ka pipe ipin 1 Ọba 18