Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 16:11-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, bí ó sì ti jókòó lórí ìtẹ́, ó lu gbogbo ilé Bááṣà pa, kò ku ọkùnrin kan sílẹ̀, bóyá ìbátan tàbí ọ̀rẹ́.

12. Bẹ́ẹ̀ ni Símírì pa gbogbo ilé Bááṣà run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ sí Bááṣà nípa ọwọ́ Jéhù wòlíì:

13. nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Bááṣà àti Élà ọmọ rẹ̀ ti ṣẹ̀ àti tí wọ́n ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀, tí wọ́n fi mú Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú, wọ́n mú u bínú nípa òrìṣà asán wọn.

14. Ìyòókù ìṣe Élà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?

15. Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Áṣà ọba Júdà, ni Ṣímírì jọba ọjọ́ méje ní Tírísà. Àwọn ọmọ ogun sì dó ti Gíbétónì, ìlú àwọn ará Fílístínì.

16. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó dó tì gbọ́ wí pé Símírì ti dìtẹ̀ sí ọba, ó sì ti pa á, wọ́n kéde Ómírì, olórí ogun, bí ọba lórí Ísírẹ́lì ní ọjọ́ náà ní ibùdó.

17. Nígbà náà ni Ómírì àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ kúrò ní Gíbétónì, wọ́n sì dó ti Tírísà.

18. Nígbà tí Ṣímírì sì ri pé a ti gba ìlú, ó sì wọ inú ààfin ilé ọba lọ, ó sì tẹ iná bọ ilé ọba lórí ara rẹ̀, ó sì kú,

19. nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀, ní ṣíṣe búburú níwájú Olúwa àti ní rírìn ní ọ̀nà Jéróbóámù àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣe àti tí ó ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀.

20. Níti ìyókù ìṣe Ṣímírì, àti ọ̀tẹ̀ rẹ̀ tí ó dì, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísiírẹ́lì?

Ka pipe ipin 1 Ọba 16