Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 15:22-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nígbà náà ni Áṣà ọba kéde ká gbogbo Júdà, kò dá ẹnìkan sí: wọ́n sì kó òkúta àti igi tí Bááṣà ń lò kúrò ní Rámà. Áṣà ọba sì fi wọ́n kọ́ Gébà ti Bẹ́ńjámínì àti Mísípà.

23. Níti ìyókù gbogbo ìṣe Áṣà, àti gbogbo agbára rẹ̀, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti àwọn ìlú tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà? Ṣùgbọ́n, ní ìgbà ogbó rẹ̀, àrùn ṣe é ní ẹṣẹ̀ rẹ̀.

24. Áṣà sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀ ní ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀. Jèhóṣáfátì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

25. Nádábù ọmọ Jéróbóámù sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún kejì Áṣà ọba Júdà, ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún méjì.

26. Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀ àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó mú Ísírẹ́lì dá.

27. Bááṣà ọmọ Áhíjà ti ilé Ísákárì sì dìtẹ̀ sí i, Bááṣà sì kọlù ú ní Gíbétónì, ìlú àwọn ará Fílístínì, nígbà tí Nádábù àti gbogbo Ísírẹ́lì dó ti Gíbétónì.

28. Bááṣà sì pa Nádábù ní ọdún kẹta Áṣà ọba Júdà, ó sì jọba ní ipò rẹ̀.

29. Ó sì ṣe, bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba ó pa gbogbo ilé Jéróbóámù, kò sì ku ẹnìkan tí ń mí fún Jéróbóámù, ṣùgbọ́n ó run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ó sọ nípa ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ Áhíjà ará Ṣílò:

30. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jéróbóámù ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀, àti nítorí tí ó ti mú Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú.

31. Níti ìyókù ìṣe Nádábù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?

32. Ogun sì wà láàrin Áṣà àti Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ wọn.

33. Ní ọdún kẹta Áṣà ọba Júdà, Bááṣà ọmọ Áhíjà sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní Tírísà, ó sì jọba ní ọdún mẹ́rìnlélógún.

34. Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà Jéróbóámù àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Ọba 15