Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 15:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nígbà náà ni Áṣà mú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó kù nínú ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ilé ọba. Ó sì fi lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Bẹni-Hádádì ọmọ Tábírímónì, ọmọ Hésíónì ọba Síríà tí ó ń gbé ní Dámásíkù.

19. Ó sì wí pé, “Jẹ́ kí májẹ̀mú kí ó wà láàrin èmi àti ìwọ, bí ó sì ti wà láàrin bàbá mi àti bàbá rẹ. Wò ó, Èmi rán ọrẹ fàdákà àti wúrà sí ọ. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, da májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Bááṣà, ọba Ísírẹ́lì, kí ó lè lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.”

20. Bẹni-Hádádì gba ti Áṣà ọba, ó sì rán àwọn alágbára olórí ogun rẹ̀ sí àwọn ìlú Ísírẹ́lì. Ó sì ṣẹ́gun Íjónì, Dánì àti Abeli-Bẹti-Máákà, àti gbogbo Kénérótì pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Náfútalì.

21. Nígbà tí Bááṣà sì gbọ́ èyí, ó sì síwọ́ kíkọ́ Rámà, ó sì lọ kúrò sí Tírísà.

22. Nígbà náà ni Áṣà ọba kéde ká gbogbo Júdà, kò dá ẹnìkan sí: wọ́n sì kó òkúta àti igi tí Bááṣà ń lò kúrò ní Rámà. Áṣà ọba sì fi wọ́n kọ́ Gébà ti Bẹ́ńjámínì àti Mísípà.

23. Níti ìyókù gbogbo ìṣe Áṣà, àti gbogbo agbára rẹ̀, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti àwọn ìlú tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà? Ṣùgbọ́n, ní ìgbà ogbó rẹ̀, àrùn ṣe é ní ẹṣẹ̀ rẹ̀.

24. Áṣà sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀ ní ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀. Jèhóṣáfátì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

25. Nádábù ọmọ Jéróbóámù sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún kejì Áṣà ọba Júdà, ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún méjì.

Ka pipe ipin 1 Ọba 15