Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 14:26-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ó sì kó ìṣúra ilé Olúwa lọ àti ìṣúra ilé ọba. Gbogbo rẹ̀ ni ó kó lọ, pẹ̀lú aṣà wúrà tí Sólómónì ti ṣe.

27. Réhóbóámù ọba sì ṣe asà idẹ ní ipò wọn, ó sì fi wọ́n sí ọwọ́ olórí àwọn olùṣọ́ tí ń sọ́ ilẹ̀kùn ilé ọba.

28. Nígbàkígbà tí ọba bá sì lọ sí ilé Olúwa Wọ́n á rù wọ́n, wọ́n á sì mú wọn padà sínú yàrá olùṣọ́.

29. Níti ìyókù ìṣe Réhóbóámù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà bí?

30. Ogun sì wà láàrin Réhóbóámù àti Jéróbóámù ní ọjọ́ wọn gbogbo.

31. Réhóbóámù sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní Ìlú Dáfídì. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámá; ará Ámónì. Ábíjà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Ọba 14