Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 14:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Wọ́n sì sin ín, gbogbo Ísírẹ́lì sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí láti ẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Ábíjà wòlíì.

19. Ìyòókù ìṣe Jéróbóámù, bí ó ti jagun, àti bí ó ti jọba, ni a kọ sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì.

20. Jéróbóámù sì jọba fún ọdún méjìlélógún, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Nádábù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

21. Réhóbóámù ọmọ Sólómónì sì jọba ní Júdà. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó sì jọba ní ọdún mọ́kànlélógún ní Jérúsálẹ́mù, ìlú tí Olúwa ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámà, ará Ámónì.

22. Júdà sì ṣe búburú níwájú Olúwa nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n ti dá, wọ́n sì mú u jowú ju gbogbo èyí tí baba wọn ti ṣe lọ.

23. Wọ́n sì tún kọ́ ibi gíga fún ara wọn, àti ère àti igbó òrìṣà lórí gbogbo òkè gíga, àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.

24. Àwọn tí ń hùwà panṣágà sì tún ń bẹ ní ilẹ̀ náà, àwọn ènìyàn náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun ìríra àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa ti lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

25. Ó sì ṣe ní ọdún karùn ún Réhóbóámù, Sísákì ọba Éjíbítì kọlu Jérúsálẹ́mù.

26. Ó sì kó ìṣúra ilé Olúwa lọ àti ìṣúra ilé ọba. Gbogbo rẹ̀ ni ó kó lọ, pẹ̀lú aṣà wúrà tí Sólómónì ti ṣe.

27. Réhóbóámù ọba sì ṣe asà idẹ ní ipò wọn, ó sì fi wọ́n sí ọwọ́ olórí àwọn olùṣọ́ tí ń sọ́ ilẹ̀kùn ilé ọba.

28. Nígbàkígbà tí ọba bá sì lọ sí ilé Olúwa Wọ́n á rù wọ́n, wọ́n á sì mú wọn padà sínú yàrá olùṣọ́.

29. Níti ìyókù ìṣe Réhóbóámù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà bí?

Ka pipe ipin 1 Ọba 14