Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 13:30-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Nígbà náà ni ó gbé òkú náà sínú ibojì ara rẹ̀, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ó ṣe, arákùnrin mi!”

31. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú rẹ̀ tán, ó sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Nígbà tí mo bá kú, ẹ sin mí ní ibojì níbi tí a sin ènìyàn Ọlọ́run sí; ẹ tẹ́ egungun mi lẹ́bàá egungun rẹ̀.

32. Nítorí iṣẹ́ tí ó jẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Olúwa sí pẹpẹ tí ó wà ní Bétélì àti sí gbogbo ojúbọ lórí ibi gíga tí ń bẹ ní àwọn ìlú Samáríà yóò wá sí ìmúṣẹ dájúdájú.”

33. Lẹ́yìn nǹkan yìí, Jéróbóámù kò padà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún yan àwọn àlùfáà sí i fún àwọn ibi gíga nínú gbogbo àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di àlùfáà, a yà á sọ́tọ̀ fún ibi gíga wọ̀nyí.

34. Èyí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jéróbóámù, èyí tí ó yọrí sí ìṣubú rẹ̀, a sì pa á run kúrò lórí ilẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Ọba 13