Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 13:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sì kíyèsii, ènìyàn Ọlọ́run kan wá láti Júdà sí Bétélì nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, bì Jéróbóámù sì ti dúró lẹ́bàá a pẹpẹ láti fi tùràrí jóná.

2. Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni Olúwa wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jòsíàh ní ilé Dáfídì. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga yìí tí ó ń mú ọrẹ wá síbẹ̀, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ”

3. Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní àmì kan wí pé: “Èyí ni àmì tí Olúwa ti kéde: kíyèsii, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù.”

4. Nígbà tí Jéróbóámù ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run, tí ó kígbe sí pẹpẹ náà ní Bétélì, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde nínú pẹpẹ, ó sì wí pé, “Ẹ mú un” ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i sì kákò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le fà á padà mọ́.

5. Lẹ́sẹ̀ kan náà, pẹpẹ ya, eérú náà sì dànù kúrò lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí àmì tí ènìyàn Ọlọ́run ti fi fún un nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

6. Nígbà náà ní ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì gbàdúrà fún mi kí ọwọ́ mi lè padà bọ̀ sípò.” Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa, ọwọ́ ọba sì padà bọ̀ sípò, ó sì padà sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

7. Ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Wá bá mi lọ ilé, kí o sì wá nǹkan jẹ, èmi yóò sì fi ẹ̀bùn fún ọ.”

8. Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run náà dá ọba lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá tilẹ̀ fún mi ní ìdajì ìní rẹ, Èmi kì yóò lọ pẹ̀lú rẹ tàbí kí èmi jẹ oúnjẹ tàbí mu omi ní ibí yìí.

9. Nítorí a ti pa á láṣẹ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tàbí padà ní ọ̀nà náà tí o gbà wá.’ ”

Ka pipe ipin 1 Ọba 13