Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 12:7-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá jẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí lónìí, kí o sì sìn wọ́n, àti kí o sì sọ ọ̀rọ̀ rere sí wọn nígbà tí ìwọ bá ń dá wọn lóhùn, wọn yóò má a ṣe ìránṣẹ́ rẹ títí láé.”

8. Ṣùgbọ́n Réhóbóámù kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín.

9. Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni a ó ṣe dá àwọn ènìyàn yí lóhùn, tí wọ́n wí fún mi pé, Ṣé kí àjàgà tí baba rẹ fi sí wa lọ́rùn kí ó fúyẹ́ díẹ̀?”

10. Àwọn ọmọdé tí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wí fún ọ pé, ‘Baba rẹ̀ mú kí àjàgà wa wúwo ṣùgbọ́n ìwọ mú kí ó fúyẹ́ díẹ̀ fún wa’; sọ fún wọn pé, ìka ọwọ́ mi kékeré nípọn ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ.

11. Baba mi ti gbé àjàgà wúwo lé e yín; Èmi yóò sì fi kún àjàgà yín. Baba mi ti fi pàsán nà yín; Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.”

12. Jéróbóámù àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wá sọ́dọ̀ Réhóbóámù ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ọba ti wí pé, “Ẹ padà tọ̀ mí wá ní ọjọ́ kẹta.”

13. Ọba sì fi ohùn líle dá àwọn ènìyàn lóhùn, ó sì kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un,

14. Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọmọdé, ó sì wí pé, “Baba mí sọ àjàgà yín di wúwo; Èmi yóò sì jẹ́ kí ó wúwo sí i; Baba mi fi pàsán nà yín; Èmi yóò fí àkéekèe nà yín.”

15. Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fi etí sí ti àwọn ènìyàn, nítorí tí ọ̀ràn náà ti ọwọ́ Olúwa wá láti mú ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún Jéróbóámù ọmọ Nébátì láti ẹnu Áhíjà ará Ṣílò ṣẹ.

16. Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn pé:ìpín wo ni àwa ní nínú Dáfídì,Ìní wo ni àwa ní nínú ọmọ Jésè?Padà sí àgọ́ rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì!Bojútó ilé ara rẹ, ìwọ Dáfídì!Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Ísírẹ́lì padà sí ilé wọn.

17. Ṣùgbọ́n fún ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé nínú ìlú Júdà, Réhóbóámù jọba lóri wọn síbẹ̀.

18. Réhóbóámù ọba rán Ádórámù jáde, ẹni tí ń ṣe olórí iṣẹ́ irú, ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa, Réhóbóámù ọba, yára láti gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì sá lọ sí Jérúsálẹ́mù.

19. Bẹ́ẹ̀ ni Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dáfídì títí di òní yìí.

20. Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ pé Jéróbóámù ti padà dé, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì pè é wá sí àjọ, wọ́n sì fi jẹ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Kò sí ẹnìkan tí ó tọ ilé Dáfídì lẹ́yìn bí kò ṣe kìkì ẹ̀yà Júdà nìkan.

21. Nígbà tí Réhóbóámù sì dé sí Jérúsálẹ́mù, ó kó gbogbo ilé Júdà jọ, àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì; ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n ń ṣe ológun, láti bá ilé Ísírẹ́lì jà àti láti mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Réhóbóámù, ọmọ Sólómónì.

Ka pipe ipin 1 Ọba 12