Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 12:16-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn pé:ìpín wo ni àwa ní nínú Dáfídì,Ìní wo ni àwa ní nínú ọmọ Jésè?Padà sí àgọ́ rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì!Bojútó ilé ara rẹ, ìwọ Dáfídì!Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Ísírẹ́lì padà sí ilé wọn.

17. Ṣùgbọ́n fún ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé nínú ìlú Júdà, Réhóbóámù jọba lóri wọn síbẹ̀.

18. Réhóbóámù ọba rán Ádórámù jáde, ẹni tí ń ṣe olórí iṣẹ́ irú, ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa, Réhóbóámù ọba, yára láti gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì sá lọ sí Jérúsálẹ́mù.

19. Bẹ́ẹ̀ ni Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dáfídì títí di òní yìí.

20. Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ pé Jéróbóámù ti padà dé, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì pè é wá sí àjọ, wọ́n sì fi jẹ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Kò sí ẹnìkan tí ó tọ ilé Dáfídì lẹ́yìn bí kò ṣe kìkì ẹ̀yà Júdà nìkan.

21. Nígbà tí Réhóbóámù sì dé sí Jérúsálẹ́mù, ó kó gbogbo ilé Júdà jọ, àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì; ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n ń ṣe ológun, láti bá ilé Ísírẹ́lì jà àti láti mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Réhóbóámù, ọmọ Sólómónì.

22. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Sémáíàh ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé:

23. “Sọ fún Réhóbóámù, ọmọ Sólómónì, ọba Júdà àti fún gbogbo ilé Júdà àti ti Bẹ́ńjámínì, àti fún àwọn ènìyàn tó kù wí pé,

24. ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ẹ má ṣe gòkè lọ láti bá àwọn arákùnrin yín jà, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì. Ẹ padà, olúkúlùkù yín sí ilé rẹ̀, nítorí nǹkan yìí láti ọ̀dọ̀ mi wá ni.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, wọ́n sì tún padà sí ilé wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

25. Nígbà náà ni Jéróbóámù kọ́ Ṣékémù ní òkè Éfúráímù, ó sì ń gbé inú rẹ̀. Láti ibẹ̀ ó sì jáde lọ, ó sì kọ́ Pénúélì.

26. Jéróbóámù rò nínú ara rẹ̀ pé, “Ìjọba náà yóò padà nísinsìnyìí sí ilé Dáfídì.

27. Bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá gòkè lọ láti ṣe ìrúbọ ní ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, wọn yóò tún fi ọkàn wọn fún Olúwa wọn, Réhóbóámù ọba Júdà. Wọn yóò sì pa mí, wọn yóò sì tún padà tọ Réhóbóámù ọba Júdà lọ.”

28. Lẹ́yìn tí ó ti gba ìmọ̀ràn, ọba sì yá ẹgbọ̀rọ̀ màlúù wúrà méjì. Ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ó ti pọ̀jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù. Àwọn Ọlọ́run yín nìyìí, Ísírẹ́lì, tí ó mú yín láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.”

29. Ó sì gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní Bétélì, àti èkejì ní Dánì.

30. Nǹkan yìí sì di ẹ̀ṣẹ̀; àwọn ènìyàn sì lọ títí dé Dánì láti sin èyí tí ó wà níbẹ̀.

31. Jéróbóámù sì kọ́ ojúbọ sórí ibi gíga, ó sì yan àwọn àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe inú àwọn ọmọ Léfì.

32. Ó sì dá àṣè sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹjọ gẹ́gẹ́ bí àṣè tí ó wà ní Júdà, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ. Ó ṣe èyí ní Bétélì, ó rú ẹbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe. Ó sì fi àwọn àlùfáà sí ibi gíga tí ó ti ṣe sí Bétélì.

33. Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹjọ, oṣù tí ó rò ní ọkàn ara rẹ̀, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó kọ́ ní Bétélì. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá àsè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì gun orí pẹpẹ náà lọ láti rú ẹbọ.

Ka pipe ipin 1 Ọba 12