Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 12:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Réhóbóámù sì lọ sí Ṣékémù, nítorí gbogbo Ísírẹ́lì ti lọ síbẹ̀ láti fi í jẹ ọba.

2. Nígbà tí Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó wà ní Éjíbítì síbẹ̀ gbọ́, nítorí tí ó ti sá kúrò níwájú Sólómónì ọba, ó sì wà ní Éjíbítì.

3. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jéróbóámù, òun àti gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì sì lọ sọ́dọ̀ Réhóbóámù, wọ́n sì wí fún un pé:

4. “Baba rẹ sọ àjàgà wa di wúwo, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mú kí ìsìn baba rẹ̀ tí ó le, àti àjàgà rẹ̀ tí ó wúwo, tí ó fi sí wa ní ọrùn kí ó fẹ́rẹ̀ díẹ̀, àwa yóò sì sìn ọ́.”

5. Réhóbóámù sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ná títí di ọjọ́ mẹ́ta, nígbà náà ni kí ẹ padà tọ̀ mí wá.” Àwọn ènìyàn náà sì lọ.

6. Nígbà náà ni Réhóbóámù ọba fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbààgbà tí ń dúró níwájú Sólómónì baba rẹ̀ nígbà tí ó wà láàyè. Ó sì béèrè pé, “Ìmọ̀ràn wo ni ẹ̀yin yóò gbà mí láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”

7. Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá jẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí lónìí, kí o sì sìn wọ́n, àti kí o sì sọ ọ̀rọ̀ rere sí wọn nígbà tí ìwọ bá ń dá wọn lóhùn, wọn yóò má a ṣe ìránṣẹ́ rẹ títí láé.”

8. Ṣùgbọ́n Réhóbóámù kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín.

9. Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni a ó ṣe dá àwọn ènìyàn yí lóhùn, tí wọ́n wí fún mi pé, Ṣé kí àjàgà tí baba rẹ fi sí wa lọ́rùn kí ó fúyẹ́ díẹ̀?”

Ka pipe ipin 1 Ọba 12