Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 9:24-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Àwọn olùtọ́ju ẹnu ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà oòrùn, ìwọ̀ oòrùn àríwá àti gúsù.

25. Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín isẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje.

26. Ṣùgbọ́n àwọn olórí olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Léfì ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìsúra ní ilé Olúwa.

27. Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Olúwa ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ; Wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.

28. Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Olúwa; wọn a má a kàá nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde.

29. Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí òlóòórìn dídùn.

30. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípo tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀.

31. Ará Léfì tí a sọ ní Mátítíhíà, àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣálúmì ará kórà ni a yàn sí ìdí dídín àkàrà ọrẹ.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 9