Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 8:5-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Gérà, Ṣéfúfánì àti Húrámù.

6. Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Éhúdì, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Gébà tí a sì lé kúrò lọ sí Mánáhátì:

7. Námánì Áhíjà àti Gérà, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Úṣà àti Áhíhúdù.

8. A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣáháráímù ní Móábù lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó Rẹ̀ sílẹ̀, Húṣímù àti Báárà.

9. Nípaṣẹ̀ ìyàwó Rẹ̀ Hódéṣì ó ní Jóbábù ṣíbíà, Méṣà, Málíkámà,

10. Jéúṣì Ṣákíà àti Mírímà. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀, olórí àwọn ìdílé.

11. Nípaṣẹ̀ Húṣímù ó ní Ábítúbù àti Élípálì.

12. Àwọn ọmọ Élípálì:Ébérì, Míṣámì, Ṣémédù (ẹni tí ó kọ́ Ónò àti Lódì pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká Rẹ̀.)

13. Pẹ̀lú Béríà àti Ṣémà, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Áíjálónì àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gátì kúrò.

14. Áhíò, Ṣásákì Jérémílò,

15. Ṣébádíà, Árádì, Édérì

16. Míkáélì Íṣífà àti Jóhà jẹ́ àwọn ọmọ Béríà.

17. Ṣébàdíáhì, Mésúlámù Hésékì, Hébérì

18. Íṣíméráì, Íṣílíáhì àti Jóbábì jẹ́ àwọn ọmọ Élípálì.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 8